Gbo
Bí a ṣe lè Dúró de Ọlọrun àti Gbẹ́kẹ̀lé Àkókò Rẹ̀

Nígbà tá a wà ni kékeré, a máa ń kọ orin ìjọ kan tí ó sọ pé: “Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, a ó mọ ohun gbogbo dáadáa, Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, a ó mọ ìdí rẹ̀.” Linda, ẹni tí ṣe iṣẹ́ oníṣàkóso ìṣúná owo fún ọ̀pọ̀ ọdún ní Guidelines Ministries, ti ní irírí kan tí kò rọrùn láti ti o kò lè lóye rárá; àrùn akàn ti hàn nínú ara rẹ̀ ni igba mẹta , tí ó sì jẹ́ kí wọ́n ṣe iṣẹ́ abẹ mẹ́rin àti itanna tó ba ìdá kan nínú tairoyidi rẹ̀ jẹ. Wọ́n tún ti ṣe iṣẹ́ abẹ ọkàn fún un àti iṣẹ́ angioplasti márùn-ún.