Gbo
Ẹ̀bùn Tó Dáa Jùlọ Tí O Le Fún Ọ̀rẹ́ Rẹ

Nígbà tí ọ̀rẹ́ bá ń ní ìrora, a máa ń fẹ́ kí ìrora náà parí. Ṣùgbọ́n a ò lè ṣàtúnṣe ọ̀pọ̀ ìṣòro, a sì sábà máa ṣe ọ̀kan lára àwọn nǹkan méjì yìí: àkọ́kọ́, a máa yàgò fún bí a ṣe lè sọ̀rọ̀ nípa ìrora náà nítorí pé a rí ara wa pé a kò lè ṣe ohunkóhun; ẹ̀kejì, a máa sọ àwọn ọ̀rọ̀ tí a ò ní ìdánilójú gẹ́gẹ́ bí, “Ó ní ìdí rere kan,” tàbí “Ohun gbogbo yóò dáa.” Ó lè jẹ́ òtítọ́, ṣùgbọ́n ó kéré gan-an ni wọ́n máa ń fúnni ní ìtùnú.